OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.