Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 38:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:

8. Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.

9. Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:

10. Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.

11. Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,ati pé n kò ní sí láàyè mọ́láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.

12. A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.

13. Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.

14. Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,mò ń ké igbe arò bí àdàbà.Mo wòkè títí ojú ń ro mí,ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.

15. Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe éOorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́.

16. OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè.

17. Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;ìwọ ni o dì mí mú,tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.

18. Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́.

19. Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́bí mo ti yìn ọ́ lónìí.Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ.

20. OLUWA yóo gbà mí là,a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

Ka pipe ipin Aisaya 38