Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 3:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,Juda sì ti ṣubú.Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀.

9. Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:Wọn kò fi bò rárá.Ègbé ni fún wọn,nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.

10. Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọnnítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.

11. Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,kò ní dára fún wọn.Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

12. Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.Ẹ̀yin eniyan mi,àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.

13. OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́

Ka pipe ipin Aisaya 3