Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 29:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò mọ̀wé kà.

13. OLUWA ní,“Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi,ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí;ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi.Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.

14. Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi,ohun ìyanu tí ó jọni lójú.Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”

15. Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?Ta ló mọ̀ wá?”

16. Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò.Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:“Kò ní ìmọ̀.”

17. Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kùtí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi elésoa óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.

Ka pipe ipin Aisaya 29