Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 28:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé,“Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni,yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára,òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú:Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an.

17. Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀,òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù,omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

18. Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo,àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán.Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri,yóo máa dé ba yín.

19. Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ.Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀,yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru.Ẹ̀rù yóo ba eniyan,tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà.

20. Ibùsùn kò ní na eniyan tán.Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora.

21. Nítorí pé OLUWA yóo dìdebí ó ti ṣe ní òkè Firasi,yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.

22. Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.

23. Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

24. ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìnlè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?

Ka pipe ipin Aisaya 28