Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 21:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀,bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà,ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun,Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.

11. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí:Ẹnìkan ń pè mí láti SeiriÓ ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o?Aṣọ́nà, àní òru ti rí?”

12. Aṣọ́nà bá dáhùn, ó ní:“Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ sì ń mọ́.Bí ẹ bá tún fẹ́ bèèrè,ẹ pada wá, kí ẹ tún wá bèèrè.”

13. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia nìyí:Ninu igbó Arabia ni ẹ óo sùn, ẹ̀yin èrò ará Didani.

14. Ẹ bu omi wá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.Ẹ gbé oúnjẹ pàdé ẹni tí ń sá fógun, ẹ̀yin ará ilẹ̀ Tema.

15. Wọ́n ń sá fún idà,wọ́n sá fún idà lójú ogun.Wọ́n ń sá fún àwọn tafàtafà,wọ́n sá fún líle ogun.

16. OLUWA sọ fún mi pé, “Kí ó tó tó ọdún kan, ní ìwọ̀n ọdún alágbàṣe kan, gbogbo ògo Kedari yóo dópin;

17. díẹ̀ ni yóo sì kù ninu àwọn tafàtafà alágbára ọmọ Kedari; nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 21