Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 21:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀.

2. Ìran tí a fi hàn mí yìí le:Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.

3. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí,gbogbo ara ní ń ro míbí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan,wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.

4. Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí;wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́.

5. Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.Ariwo bá ta pé“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!Ẹ fepo pa asà yín.”

6. Nítorí OLUWA wí fún mi pé:“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí.

7. Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣintí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí ití àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,tí àwọn kan gun ràkúnmí,kí ó fara balẹ̀ dáradára,kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”

8. Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru.

9. Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀,wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,ó ti wó lulẹ̀ patapata.”

Ka pipe ipin Aisaya 21