Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 19:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,n óo sọ ète wọn di òfo.Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.

4. Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

5. Omi odò Naili yóo gbẹ,yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀.

6. Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:Gbogbo koríko odò yóo rà.

7. Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù.

8. Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Nailiyóo ṣọ̀fọ̀,wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora.

9. Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun.

10. Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe.

11. Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani;ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan.Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé,“Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí,ọmọ àwọn ọba àtijọ́.”

12. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà?Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ,kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́.

13. Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀,àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn;àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà.

14. OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn,wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀,bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀.

15. Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti,kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù,kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan.

16. Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú.

Ka pipe ipin Aisaya 19