Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 19:22-25 BIBELI MIMỌ (BM)

22. OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.

23. Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.

24. Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi.

25. Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.”

Ka pipe ipin Aisaya 19