Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 19:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti.

18. Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun.Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn.

19. Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀.

20. Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.

21. OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.

22. OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.

23. Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.

Ka pipe ipin Aisaya 19