Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:12-28 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

13. Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.

14. Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.

15. “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbaduran kò ní gbọ́;nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,

16. Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.

17. Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”

18. OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,yóo di funfun bí ẹfun.Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.

19. Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.

20. Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun;idà ni yóo run yín.”Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.

21. Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó,ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn.

22. Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.

23. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.

24. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.

25. Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.

26. N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”

27. A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.

28. Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.

Ka pipe ipin Aisaya 1