Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA ní,“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.

12. Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

13. Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.

14. Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.

15. “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbaduran kò ní gbọ́;nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,

16. Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.

17. Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”

18. OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,yóo di funfun bí ẹfun.Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.

Ka pipe ipin Aisaya 1