Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 4:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì gbé àmì ìkọlà, èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú.

12. Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún ṣá, ṣùgbọ́n ti wọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.

13. Ìlérí fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀, pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́.

14. Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá ṣe ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára:

15. Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: Ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.

16. Nítorí náà ni ó ṣe gbé e karí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-òfẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ẹni tí í se baba gbogbo wa pátapáta,

17. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ se baba orílẹ̀ èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà;

18. Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Ábúráhámù gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyi tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú ọmọ rẹ̀ yóò rí.”

19. Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó ro ti ara òun tìkarárẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí tí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rún-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sárà:

20. Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run;

21. Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀.

22. Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un.

Ka pipe ipin Róòmù 4