Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 3:19-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

20. Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

21. Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì;

22. Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀:

23. Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run:

24. Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù:

25. Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:

26. Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́.

27. Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.

28. Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.

29. Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:

30. Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

31. Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.

Ka pipe ipin Róòmù 3