Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 3:10-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan

11. Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

12. Gbogbo wọn ni ó ti yapa,wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;kò sí ẹni tí ń ṣe rere,kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

13. “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní Ọ̀fun wọn:ahọ́n wọn di aláìlérè; kò sí ẹni ìtànjẹ.”“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

14. “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

15. “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:

16. Ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

17. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”

18. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

19. Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

20. Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

21. Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì;

22. Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀:

23. Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run:

24. Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù:

25. Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:

26. Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́.

27. Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.

Ka pipe ipin Róòmù 3