Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 11:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé Ọlọ́run ti yà mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà. Mo ń tẹnumọ́ ọn gidigidi mo sì ń rán àwọn Júù létí nípa rẹ̀ nígbákùúgbà tí ààyè bá wà.

14. Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn.

15. Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì. Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé (àwọn aláìkọlà) láti fún wọn ní ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì. Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́.

16. Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú. Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú.

17. Ṣùgbọ́n a ti ké díẹ̀ nínú ẹ̀ka Ábúráhámù, tí í ṣe àwọn Júù kúrò. Ẹ̀yin aláìkọlà, tí a lè wí pé ó jẹ́ ẹ̀ka igi búburú ni a fi sí ipò àwọn Júù. Nítorí náà, nísinsinyí, í se é ṣe fún yín láti gba ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìpinnu fún Ábúráhámù àti àwọn ọmọ rẹ̀, èyí ni pé, ẹ ń pín nínú oúnjẹ ọlọ́ràá tí ó jẹ́ ti igi àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run.

18. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò. Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí. Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò.

19. Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ”

20. Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́. Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́. Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi.

21. Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí.

22. Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.

Ka pipe ipin Róòmù 11