Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 10:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà; Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀.

13. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

14. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù?

15. Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere!”

16. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìn rere. Nítorí Ìsáià wí pé, “Olúwa, tali ó gba ìyìn wa gbọ́?”

17. Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18. Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ayé.”

19. Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ísírẹ́lì kò ha mọ̀ bí? Mósè ni ó kọ́ wí pé,“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”

20. Ṣùgbọ́n Ìsáià tilẹ̀ láyà, ó wí pé,“Àwọn tí kò wá mi rí mi;Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”

21. Ṣùgbọ́n nípa ti Ísírẹ́lì ni ó wí pé,“Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọnaláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”

Ka pipe ipin Róòmù 10