Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 1:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ọlọ́run, ẹni tí èmí ń sìn tí mo sì fi gbogbo ọkàn mi jìn fún un láti máa wàásù ìyìnrere ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsinmi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi

10. nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó sí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

11. Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa,

12. èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

13. Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù.

14. Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Gíríkì àti sí àwọn ẹlòmíràn tí kì í se Gíríkì, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aláìgbọ́n.

15. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Róòmù àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìn rere Ọlọ́run sí i yín.

16. Èmi kò tijú ìyìn rere Jésù, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún aláìkọlà pẹ̀lú.

17. Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́rùn ti farahàn, òdodo Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

18. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.

19. Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn.

20. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

Ka pipe ipin Róòmù 1