Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 1:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń forí balẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

26. Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́ ìwàkíwà: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò àdánidá padà sí èyí tí ó lòdì sí ti àdánidá:

27. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

28. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe:

29. Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àránkan; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà-búburú; wọ́n jẹ́ afi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́.

30. Asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, akóríra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí,

31. Aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú:

32. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

Ka pipe ipin Róòmù 1