Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 9:31-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.

32. Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí-èṣù tọ Jesu wá.

33. Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”

34. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde.”

35. Jésù sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìyìn rere ìjọba, ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn.

36. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.

37. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan

38. Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Ka pipe ipin Mátíù 9