Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 9:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.”

30. Ojú wọn sì là; Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan ki o mọ̀ nípa èyí.”

31. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.

32. Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí-èṣù tọ Jesu wá.

33. Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”

34. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde.”

35. Jésù sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìyìn rere ìjọba, ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn.

Ka pipe ipin Mátíù 9