Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 8:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Jésù sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnì kan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlúfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mósè pa laṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”

5. Nígbà tí Jésù sì wọ̀ Kápánámù, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

6. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

7. Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”

8. Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.

9. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹnì kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

10. Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.

11. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìha ìlà-oòrùn àti ìhà iwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Ábúráhámù àti Ísáákì àti Jákọ́bù jẹun ní ìjọba ọ̀run.

12. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

Ka pipe ipin Mátíù 8