Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 8:15-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn.

16. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.

17. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:“Òun tikara rẹ̀ gbà àìlera wa,ó sì ń ru àrùn wa.”

18. Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọdá sí òdìkejì adágún.

19. Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

20. Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

21. Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”

22. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

23. Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e.

24. Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jésù ń sùn.

25. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, ‘gbà wá,’ àwa yóò rì.”

26. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí. gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́.

27. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀?”

28. Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀.

29. Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”

30. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn

Ka pipe ipin Mátíù 8