Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 8:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìha ìlà-oòrùn àti ìhà iwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Ábúráhámù àti Ísáákì àti Jákọ́bù jẹun ní ìjọba ọ̀run.

12. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

13. Nítorí náà Jésù sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà lára dá ní wákàtí kan náà.

14. Nígbà tí Jésù sì dé ilé Pétérù, ìyá ìyàwó Pétérù dùbúlẹ̀ àìsàn ibà.

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn.

16. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.

17. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:“Òun tikara rẹ̀ gbà àìlera wa,ó sì ń ru àrùn wa.”

18. Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọdá sí òdìkejì adágún.

19. Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

20. Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

21. Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”

22. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

23. Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e.

24. Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jésù ń sùn.

Ka pipe ipin Mátíù 8