Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 6:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní sínágọ́gù àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ.

7. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó titorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn.

8. Ẹ má ṣe dà bí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

9. “Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,ọ̀wọ̀ fún orukọ yín,

10. Kí ìjọba yín dé,Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣení ayé bí ti ọ̀run.

11. Ẹ fún wa ní oúnjẹ oòjọ́ wa lónìí

12. Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,Bí àwa ti ń dárí ji àwọn ajigbésè wa,

13. Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdẹwò,Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

14. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dárí jì yín.

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò níí dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

16. “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fi hàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún.

17. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradárá

18. Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sìí Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ.

19. “Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le dípẹtà àti ibi tí àwọn olèlè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ.

Ka pipe ipin Mátíù 6