Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 5:30-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.

31. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ gbọdọ̀ fún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’

32. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀, àfi nítorí àgbèrè, mú un se àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó ṣe àgbèrè.

33. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàani pé; ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búrá èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ sí Olúwa ṣẹ.’

34. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, Ẹ má ṣe búra rárá,: ìbáà ṣe ìfi-ọ̀run-búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni.

35. Tàbí ìfi-ayé-búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerúsálémù, nítorí olórí ìlú Ọba Ńlá ni.

36. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.

37. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

38. “Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’

39. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnì kan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú.

40. Bí ẹnì kan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.

41. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.

42. Fi fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó fẹ́ ya láti lọ́wọ́ rẹ.

43. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Fẹ́ràn aládúgbo rẹ, kí ìwọ sì kórírà ọ̀ta rẹ̀.’

44. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀ta yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín,

45. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín bi ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo.

Ka pipe ipin Mátíù 5