Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 5:21-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’

22. Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arakùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà’ yóò fara hàn níwájú Sahẹ́ńdìrì; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23. “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá ṣíwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ.

24. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrin ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.

25. “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídajọ lọ́wọ́, onídájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀sọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú.

26. Lóòótọ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títítí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

27. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’

28. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìrinrin kan ní ìwòkuwò, ti bà a ṣe panṣágà ná ní ọkàn rẹ̀.

29. Bí ojú rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sínú iná ọ̀run àpáàdì.

30. Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.

31. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ gbọdọ̀ fún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’

32. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀, àfi nítorí àgbèrè, mú un se àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó ṣe àgbèrè.

33. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàani pé; ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búrá èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ sí Olúwa ṣẹ.’

34. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, Ẹ má ṣe búra rárá,: ìbáà ṣe ìfi-ọ̀run-búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni.

35. Tàbí ìfi-ayé-búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerúsálémù, nítorí olórí ìlú Ọba Ńlá ni.

36. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.

37. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

Ka pipe ipin Mátíù 5