Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 3:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònú-pìwàdà.

9. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Ábúráhámù ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Ábúráhámù.

10. Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò gé lulẹ̀ ti a ó sì jù wọn sínú iná.

11. “Èmi fi omi bamitíìsì yín fún ìrónúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitíìsì yín.

12. Ẹni ti ìmúga ìpakà Rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó ọkà rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

13. Nígbà náà ni Jésù ti Gálílì wá sí odò Jọ́dánì kí Jòhánù báà lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

14. Ṣùgbọ́n Jòhánù kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ì bá ṣe ìbamitíìsì fún mi, ṣé ìwọ tọ̀ mí wá fún ìbamitíìsì?”

15. Jésù sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, ní torí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù gbà, ó sì ṣe ìbamitíìsì fún un.

16. Bí a si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún Jésù tán, Ó jáde láti inú omi. Ní àkókò náà ọ̀run sí sílẹ̀, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà àti bi mọ̀nàmọ́ná sórí rẹ̀.

Ka pipe ipin Mátíù 3