Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:36-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.

37. Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ” síbẹ̀.

38. Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀.

39. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé:

40. “Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ-Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”

41. Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà.

42. Wọ́n kẹ́gàn Rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Ísírẹ̀lì? Sọ̀ kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsìn yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́.

43. Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”

44. Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.

45. Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi sú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsàn-án ọjọ́

46. Níwọ̀n wákàtí kẹsàn-án ní Jésù sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Èlí, Èlí, Làmá Sàbákitànì” (ní èdè Hébérù). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, è é ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

47. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.

48. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànrìkàn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu.

49. Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbà á là.”

50. Nígbà tí Jésù sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.

51. Lójú kan náà aṣọ ìkélé tẹ̀ḿpìlì fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán.

52. Àwọn isà òkú sì sí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn olódodo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti kú sì tún jíǹde.

Ka pipe ipin Mátíù 27