Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:15-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jésù lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.

16. Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

17. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àkàrà àìwú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jésù wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

18. Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”

19. Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

20. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jésù ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá,

21. nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”

22. Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”

23. Jésù dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn.

24. Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”

25. Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Ráábì, èmi ni bí?”Jésù sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i”

26. Bí wọ́n ti ń jẹun, Jésù sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

27. Bákan náà, ó sì mú aago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sí fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.

28. Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi, tí ó ń ṣe májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

29. Sì kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní titun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”

30. Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Ólífì.

31. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé:“ ‘Èmi yóò kọlu olùsọ́ àgùntàna ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’

32. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Gálílì.”

Ka pipe ipin Mátíù 26