Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni.

13. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìn rere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”

14. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn àpósítélì méjìlá ti à ń pè ní Júdásì Ìskáríọ́tù lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.

15. Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jésù lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.

16. Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

17. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àkàrà àìwú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jésù wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

18. Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”

19. Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

20. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jésù ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá,

21. nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”

22. Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”

23. Jésù dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn.

24. Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”

Ka pipe ipin Mátíù 26