Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn ẹlòmíràn tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.

44. Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

45. Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ òwe Jésù, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn.

46. Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí wòlíì.

Ka pipe ipin Mátíù 21