Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ní ìdà kejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.”

27. Nítorí náà wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.

28. “Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣíṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’

Ka pipe ipin Mátíù 21