Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 2:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, ni àkókò ọba Hẹ́rọ́dù, àwọn amoye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálémù.

2. Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrun, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

3. Nígbà tí ọba Hẹ́rọ́dù sì gbọ́ èyí, ìdáàmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerúsálémù pẹ̀lú rẹ̀

4. Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfàá àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kírísítì?

5. Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

6. “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Jùdíà,ìwọ kò kéré jù láàrin àwọn ọmọ aládé Jùdíà;nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,Ẹni ti yóò ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn mi.’ ”

7. Nígbà náà ni Hérọ́dù ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan-an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.

Ka pipe ipin Mátíù 2