Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 19:19-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20. Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”

21. Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23. Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”

24. Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

26. Jésù sì tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Bí o bá jẹ́ ti ènìyàn ni, eléyìí sòro. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ti Ọlọ́run ni, ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

27. Pétérù sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé Ọ. Kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

28. Jésù dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ-Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ̀ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.

29. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun.

30. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣíwájú nísinsìn yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì ṣíwájú.’

Ka pipe ipin Mátíù 19