Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 18:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ̀ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò.

16. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà.

17. Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó-òde.

18. “Àti pé mo tún sọ èyí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhùn ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run.

19. “Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín.

20. Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrin wọn níbẹ̀.”

21. Nígbà náà ni Pétérù wá sọ́dọ̀ Jésù, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”

22. Jésù dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í se ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje;

23. “Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ se ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀.

24. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún (10,000) talẹ́ńtì.

Ka pipe ipin Mátíù 18