Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 18:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”

2. Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrin wọn.

3. Ó wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run.

4. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run.

5. “Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.

6. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọkékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi òkun.

7. “Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípaṣẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!

8. Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé.

9. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpádì.

10. “Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú bẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń láti lọ wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.

11. Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

12. “Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí?

13. Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ?

14. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

15. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ̀ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò.

Ka pipe ipin Mátíù 18