Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 16:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?

10. Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì (4,000) ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ?

11. È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí.”

12. Nígbà náà ni ó ṣẹ̀sẹ̀ wá yé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyè sára, bí kò se tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí.

13. Nígbà tí Jésù sì dé Kesaríà-Fílípì, ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

14. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Jòhánù onítẹ̀bọ́mì ni, àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremáyà ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

15. “Ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ìwọ rò pé mo jẹ́?”

16. Símónì Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè”

17. Jésù sì wí fún un pé, “Alábùnkún-fún ni ìwọ Símónì ọmọ Jónà, nítorí ènìyàn kọ́ ló fi èyí hàn bí kò se Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

18. Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Pétérù àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú kì yóò lè borí rẹ̀.

19. Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhùn tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”

20. Nígbà náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kírísítì náà.

Ka pipe ipin Mátíù 16