Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 16:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní òwúrọ̀, ‘Èyin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí.

4. Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè àmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkan kan ní àmì bí kò ṣe àmì Jónà.” Nígbà náà ni Jésù fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

5. Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́.

6. Jésù sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyè sára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”

7. Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárin ara wọn nítorí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́.

8. Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?

9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?

Ka pipe ipin Mátíù 16