Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èé ṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

11. Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.

12. Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà.

13. Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:“Ní ti rírí, wọn kò rí;ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

14. Sí ara wọn ni a ti mú àṣọtẹ́lẹ̀ wòlíì Àìsáyà ṣẹ:“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọn kì yóò sì yé yín;ní rírí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.

Ka pipe ipin Mátíù 13