Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.

12. Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà.

13. Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:“Ní ti rírí, wọn kò rí;ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

14. Sí ara wọn ni a ti mú àṣọtẹ́lẹ̀ wòlíì Àìsáyà ṣẹ:“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọn kì yóò sì yé yín;ní rírí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.

15. Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́etí wọn sì wúwo láti gbọ́ojú wọn ni wọ́n sì dìnítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn ríkí wọ́n má ba à fi ètí wọn gbọ́kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òge,kí wọn má ba à yí padà, kí èmi ba à le mú wọn lára dá.’

Ka pipe ipin Mátíù 13