Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan náà, Jésù kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí òkun.

2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀-ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí òkun.

3. Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.

4. Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́.

5. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbà sókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọ sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.

7. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárin ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.

8. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rún, òmiràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ó ti gbìn.

9. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èé ṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

Ka pipe ipin Mátíù 13