Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 12:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, tí kì yóò dì í mú, kí ó sì fà á jáde.

12. Ǹjẹ́ mélòó mèlòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.”

13. Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ìkejì.

14. Síbẹ̀ àwọn Farisí jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

15. Ṣùgbọ́n Jésù mọ, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

16. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ẹni ti òun jẹ́.

17. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Àìsáyà sọ nípa rẹ̀ pé:

18. “Ẹ wo ìránṣẹ mi ẹni tí mo yàn.Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo.

19. Òun kì yóò jà. bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.

20. Ìyẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ fò ni kí yóò ṣẹ́,bẹ́ẹ̀ ni kì yóò pa iná fìtílà tí ó rú èéfín.Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìsẹ́gun.

21. Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo ayé yóò fi ìrètí wọn sí.”

22. Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹmí-èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jésù sì mú un lára dá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

23. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dáfídì bí?”

Ka pipe ipin Mátíù 12