Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 1:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, ańgẹ́lì Olúwa yọ sí i ní oju àlá, ó wí pé, “Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má fòyà láti fi Màríà ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.

21. Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé:

23. “Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, a ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Èmánúẹ́lì,’ ” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”

24. Nígbà tí Jósẹ́fù jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí ańgẹ́lì Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Màríà wá sílé rẹ̀ ní aya.

25. Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títítí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jésù.

Ka pipe ipin Mátíù 1