Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 1:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Ábúráhámù dé orí Dáfídì, ìran mẹ́rìnlà á láti orí Dáfídì títí dé ìkólọ sí Bábílónì, àti ìran mẹ́rìnlà láti ìkólọ títí dé orí Kírísítì.

18. Bí a ṣe bí Jésù nì yìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrin Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

19. Nítorí Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòótọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

20. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, ańgẹ́lì Olúwa yọ sí i ní oju àlá, ó wí pé, “Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má fòyà láti fi Màríà ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.

21. Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé:

Ka pipe ipin Mátíù 1