Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 9:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.

9. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ-Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.

10. Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.

11. Nísinsìnyìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́-ófin ń sọ wí pé, “Èlíjà ní yóò kọ́kọ́ dé.”

12. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Èlíjà yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ-Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”

14. Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹ̀ṣẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́-òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn.

15. Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.

16. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyàn-jiyàn?”

17. Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.

18. Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”

19. Ó sì dá wọn lóhun, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”

20. Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu.

21. Jésù béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”

22. Nígbàkúùgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná ati sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Máàkù 9