Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 5:14-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sá lọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó sẹlẹ̀.

15. Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n.

16. Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.

17. Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jésù pé kí ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀.

18. Bí Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ.

19. Jésù kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.”

20. Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapolisi nípa ohun ńlá tí Jésù ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.

21. Nígbà tí Jésù sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí òkun.

22. Ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù tí à ń pè ni Jáírù wá sọ́dọ̀ Jésù, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

23. Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.”

24. Jésù sì ń bá a lọ.Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

25. Obìnrin kan sì wà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá.

26. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i.

27. Nígbà tí ó sì gburo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.

28. Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá ṣá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

Ka pipe ipin Máàkù 5