Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

9. Jésù sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́”

10. Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léérèè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”

11. Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láàyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.

12. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé,“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

13. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín?

14. Afúrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.

15. Àwọn èṣo tó bọ́ sí ojú ọ̀nà líle, ni àwọn ọlọ́kan líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́.

16. Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpata, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

17. Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọn a wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibínu bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọn a kọsẹ̀.

18. Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á.

19. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso.

Ka pipe ipin Máàkù 4