Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jónà, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.

7. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrin ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúngbìn náà kò le so èso.

8. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

9. Jésù sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́”

10. Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léérèè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”

11. Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láàyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.

12. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé,“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

13. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín?

14. Afúrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.

Ka pipe ipin Máàkù 4