Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jésù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ní létí òkun Àwọn ijọ̀ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí òkun.

2. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:

3. “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.

4. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.

5. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpátá, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hú jáde.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jónà, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.

7. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrin ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúngbìn náà kò le so èso.

8. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

9. Jésù sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́”

10. Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léérèè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”

11. Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láàyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.

12. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé,“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

Ka pipe ipin Máàkù 4